Matthew 21:12 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu bá wọ inú Tẹmpili lọ, ó lé gbogbo àwọn tí wọn ń tà, tí wọn ń rà kúrò níbẹ̀. Ó ti tabili àwọn tí wọn ń ṣe pàṣípààrọ̀ owó ṣubú. Ó da ìsọ̀ àwọn tí wọn ń ta ẹyẹlé rú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu si wọ̀ inu tẹmpili Ọlọrun lọ, o si lé gbogbo awọn ẹniti ntà, ati awọn ti nrà ni tẹmpili jade, o si yi tabili awọn onipaṣiparọ owo danù, ati ijoko awọn ti ntà ẹiyẹle.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì wọ inú tẹ́ḿpì Ọlọ́run. Ó sì lé àwọn ti ń tà àti àwọn ń rà níbẹ̀ jáde. Ó yí tábìlì àwọn onípàsípààrọ̀ owó dànù, àti tábìlì àwọn tí ó ń ta ẹyẹlẹ́.