Matthew 21:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Jesu dé inú Tẹmpili, bí ó ti ń kọ́ àwọn eniyan lẹ́kọ̀ọ́, àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbààgbà ìlú wá sọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n bi í pé, “Irú agbára wo ni o fi ń ṣe nǹkan wọnyi? Ta ni ó sì fún ọ ní agbára náà?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si de inu tẹmpili, awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá sọdọ rẹ̀ bi o ti nkọ́ awọn enia; nwọn wipe, Aṣẹ wo ni iwọ fi nṣe nkan wọnyi? tali o si fun ọ li aṣẹ yi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù wọ tẹ̀ḿpìlì, nígbà tí ó ń kọ́ni, àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù tọ̀ ọ́ wá. Wọ́n béèrè pé “nípa àṣẹ wo ni o fi ń ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí? Ta ni ó sì fún ọ ni àsẹ yìí?”