Matthew 21:30 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọkunrin náà lọ sọ́dọ̀ ọmọ keji, ó sọ fún un bí ó ti sọ fún ekinni. Ọmọ náà dá a lóhùn pé, ‘Ó dára, mo gbọ́, Baba!’ Ṣugbọn kò lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tọ̀ ekeji wá, o si wi bẹ̃ gẹgẹ. O si dahùn wi fun u pe, Emi o lọ, baba: kò si lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà ni baba yìí tún sọ fún èyi àbúrò pé, ‘Lọ ṣiṣẹ́ ní oko.’ Ọmọ náà sì sọ pé, ‘Èmi yóò lọ, baba,’ ṣùgbọ́n kò lọ rárá.