Matthew 21:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ninu àwọn mejeeji, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba rẹ̀?” Wọ́n ní, “Ekinni ni.” Jesu bá sọ fún wọn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó yóo ṣáájú yín wọ ìjọba Ọlọrun.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ninu awọn mejeji, ewo li o ṣe ifẹ baba rẹ̀? Nwọn wi fun u pe, Eyi ekini. Jesu si wi fun wọn pe, Lõtọ ni mo wi fun nyin, awọn agbowode ati awọn panṣaga ṣiwaju nyin lọ si ijọba Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nínú àwọn méjèèjì yìí, èwo ni ó ṣe ìfẹ́ baba wọn?” Gbogbo wọn sì fohùn ṣọ̀kan pé, “Èyí ẹ̀gbọ́n ni.” Jésù wí fún wọn pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún yín, àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà yóò wọ ìjọba ọ̀run ṣíwájú yín.