Matthew 21:32 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nítorí Johanu wá sọ́dọ̀ yín ní ọ̀nà òdodo, ṣugbọn ẹ kò gbà á gbọ́. Ṣugbọn àwọn agbowó-odè ati àwọn aṣẹ́wó gbà á gbọ́. Lẹ́yìn tí ẹ rí èyí, ẹ kò ronupiwada kí ẹ gbà á gbọ́.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitori Johanu ba ọ̀na ododo tọ̀ nyin wá, ẹnyin kò si gbà a gbọ́: ṣugbọn awọn agbowode ati awọn panṣaga gbà a gbọ́: ṣugbọn ẹnyin, nigbati ẹnyin si ri i, ẹ kò ronupiwada nikẹhin, ki ẹ le gbà a gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí Jòhánù tọ́ yin wá láti fi ọ̀nà òdodo hàn yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbà á gbọ́, ṣùgbọ́n àwọn agbowó-òde àti àwọn panṣágà ronúpìwàdà, bí ó tilẹ̀ ṣe pé ẹ rí àwọn ohun tí ń ṣẹlẹ̀ wọ̀nyí, ẹ kọ̀ láti ronúpìwàdà, ẹ kò gbà á gbọ́.”