Matthew 21:45 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi gbọ́ àwọn òwe wọnyi, wọ́n mọ̀ pé àwọn ni ó ń bá wí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati awọn olori alufa ati awọn Farisi gbọ́ owe rẹ̀ nwọn woye pe awọn li o mba wi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí àwọn olórí àlùfáà àti àwọn Farisí gbọ́ òwe Jésù, wọ́n mọ̀ wí pé ó ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn.