Matthew 22:10 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àwọn ẹrú náà bá lọ sí ìgboro, wọ́n kó gbogbo àwọn tí wọ́n rí wá, ati àwọn eniyan rere, ati àwọn eniyan burúkú. Oniruuru eniyan bá kún ibi àsè igbeyawo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bẹ̃li awọn ọmọ-ọdọ wọnni si jade lọ si ọ̀na opópo, nwọn si kó gbogbo awọn ẹniti nwọn ri jọ, ati buburu ati rere: ibi ase iyawo si kún fun awọn ti o wá jẹun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ náà sì jáde lọ sí òpópónà. Wọ́n sì mú oríṣìíríṣìí ènìyàn tí wọ́n lè rí wá, àwọn tí ò dára àti àwọn tí kò dára, ilé àṣè ìyàwó sì kún fún àlejò.