Matthew 22:16 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n bá rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹlu àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hẹrọdu láti bi í pé, “Olùkọ́ni, a mọ̀ pé olóòótọ́ ni ọ́, ati pé pẹlu òtítọ́ ni o fi ń kọ́ eniyan ní ọ̀nà Ọlọrun; o kì í ṣe ojuṣaaju fún ẹnikẹ́ni nítorí o kì í wojú eniyan kí o tó sọ̀rọ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn si rán awọn ọmọ-ẹhin wọn pẹlu awọn ọmọ-ẹhin Herodu lọ sọdọ rẹ̀, wipe, Olukọni, awa mọ̀ pe olotitọ ni iwọ, iwọ̀ si nkọni li ọ̀na Ọlọrun li otitọ, bẹ̃ni iwọ ki iwoju ẹnikẹni: nitoriti iwọ kì iṣe ojuṣaju enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì rán àwọn ọmọ-ẹ̀yìn wọn pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Hérọ́dù lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ pé, “Olùkọ́, àwa mọ̀ pé olótìítọ́ ni ìwọ, ìwọ sì ń kọ́ni ní ọ̀nà Ọlọ́run ní òtítọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ìwọ kì í wo ojú ẹnikẹ́ni; nítorí tí ìwọ kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn.