Matthew 22:21 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Wọ́n dá a lóhùn pé, “Ti Kesari ni.” Ó bá sọ fún wọn pé, “Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, ẹ fi ohun tí ó jẹ́ ti Kesari fún Kesari, kí ẹ sì fi ohun tíí ṣe ti Ọlọrun fún Ọlọrun.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nwọn wi fun u pe, Ti Kesari ni. Nigbana li o wi fun wọn pe, Njẹ ẹ fi ohun ti iṣe ti Kesari fun Kesari, ati ohun ti iṣe ti Ọlọrun fun Ọlọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n sì dáhùn pé, “Ti Késárì ni.” “Nígbà náà ni ó wí fún wọn pé,” “Ẹ fi èyí tí í ṣe ti Késárì fún Késárì, ẹ sì fi èyí ti ṣe ti Ọlọ́run fún Ọlọ́run.”