Matthew 22:25 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò meje kan wà lọ́dọ̀ wa. Ekinni gbé iyawo, láìpẹ́ ó kú. Nígbà tí kò bí ọmọ, ó fi iyawo rẹ̀ sílẹ̀ fún àbúrò rẹ̀.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Awọn arakunrin meje kan ti wà lọdọ wa: eyi ekini lẹhin igbati o gbé aya rẹ̀ ni iyawo, o kú, bi kò ti ni irúọmọ, o fi aya rẹ̀ silẹ fun arakunrin rẹ̀:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, láàrin wa níhìn-in yìí, ìdílé kan wà tí ó ní arákùnrin méje. Èyí èkínní nínú wọn gbéyàwó, lẹ́yìn náà ó kú láìlọ́mọ. Nítorí náà ìyàwó rẹ̀ di ìyàwó arákùnrin kejì.