Matthew 22:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí pé ní àkókò ajinde kò ní sí pé à ń gbé iyawo, tabi pé à ń fi ọmọ fún ọkọ; nítorí bí àwọn angẹli ti rí ní ọ̀run ni wọn yóo rí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitoripe li ajinde okú, nwọn kì igbeyawo, a kì si fi wọn funni ni igbeyawo, ṣugbọn nwọn dabi awọn angẹli Ọlọrun li ọrun.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí ní àjíǹde kò ní sí ìgbéyàwó, a kò sì ní fi í fún ni ní ìyàwó. Gbogbo ènìyàn yóò sì dàbí àwọn ańgẹ́lì ní ọ̀run.