Matthew 22:4 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tún rán àwọn ẹrú mìíràn, kí wọ́n sọ fún àwọn tí a ti pè pé, ‘Mo ti se àsè tán; mo ti pa mààlúù ati àwọn ẹran ọlọ́ràá; mo ti ṣe ètò gbogbo tán. Ẹ wá sí ibi igbeyawo.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tún rán awọn ọmọ-ọdọ miran, wipe, Ẹ wi fun awọn ti a pè pe, Wò o, mo se onjẹ mi tan: a pa malu ati gbogbo ẹran abọpa mi, a si ṣe ohun gbogbo tan: ẹ wá si ibi iyawo.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lẹ́yìn náà ó tún rán àwọn ọmọ-ọ̀dọ̀ mìíràn pé, ‘Ẹ sọ fún àwọn tí mo ti pè wí pé, mo ti se àsè náà tán. A pa màlúù àti ẹran àbọ́pa mi, a ti ṣe ohun gbogbo tán, ẹ wa sí ibi àsè ìgbéyáwó.’