Matthew 23:15 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Ẹ gbé! Ẹ̀yin amòfin ati ẹ̀yin Farisi, ẹ̀yin aláṣehàn, nítorí ẹ̀ ń la òkun ati oríṣìíríṣìí ìlú kọjá láti mú ẹyọ ẹnìkan láti orílẹ̀-èdè mìíràn wọ ẹ̀sìn yín. Nígbà tí ó bá ti wọ ẹ̀sìn tán, ẹ wá sọ ọ́ di ẹni ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po meji ju ẹ̀yin alára lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin nyi okun ati ilẹ ká lati sọ enia kan di alawọṣe; nigbati o ba si di bẹ̃ tan, ẹnyin a sọ ọ di ọmọ ọrun apadi nigba meji ju ara nyin lọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ègbé ni fún yín ẹ̀yin olùkọ́ òfin àti Farisí, ẹ̀yin àgàbàgebè! nítorí ẹ̀yin rin yí ilẹ̀ àti òkun ká láti yí ẹnì kan lọ́kàn padà, ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń sọ ọ́ di ọmọ ọ̀run àpáàdì ní ìlọ́po méjì ju ẹ̀yin pàápàá.