Matthew 23:35 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ óo ṣe gbogbo nǹkan wọnyi kí ẹ lè fi orí gba ẹ̀bi ikú gbogbo eniyan rere tí ẹ ti ta ẹ̀jẹ̀ wọn sílẹ̀; ohun tí ó ṣẹ̀ láti orí Abeli, ẹni rere títí fi dé orí Sakaraya, ọmọ Berekaya, tí ẹ pa láàrin àgọ́ mímọ́ ati pẹpẹ ìrúbọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki gbogbo ẹ̀jẹ awọn olõtọ, ti a ti ta silẹ li aiye, ba le wá sori nyin, lati ẹ̀jẹ Abeli olododo titi de ẹ̀jẹ Sakariah ọmọ Barakiah, ẹniti ẹnyin pa larin tẹmpili ati pẹpẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ pa, láti ẹ̀jẹ̀ Ábélì títí dé ẹ̀jẹ̀ Ṣákaráyà ọmọ Berekáyà ẹni tí ẹ pa nínú Tẹ́ḿpìlì láàrin ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.