Matthew 23:37 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Jerusalẹmu! Jerusalẹmu! Ìwọ tí ò ń pa àwọn wolii, tí ò ń sọ àwọn tí a rán sí ọ ní òkúta pa! Ìgbà mélòó ni mo ti fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ, bí adìẹ tí ń kó àwọn ọmọ rẹ̀ sí abẹ́! Ṣugbọn o kọ̀ fún mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jerusalemu, Jerusalemu, iwọ ti o pa awọn wolĩ, ti o si sọ okuta lù awọn ti a rán si ọ pa, igba melo li emi nfẹ radọ bò awọn ọmọ rẹ, bi agbebọ̀ ti iradọ bò awọn ọmọ rẹ̀ labẹ apá rẹ̀, ṣugbọn ẹnyin kò fẹ!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Jerúsálémù, Jerúsálémù, ìlú tí ó pa àwọn wòlíì, tí ó sì sọ òkúta lu àwọn tí a rán sí i. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni èmi tí ń fẹ́ kó àwọn ọmọ rẹ jọ pọ̀ gẹ́gẹ́ bí àgbébọ̀ adíyẹ̀ ti í dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lábẹ́ ìyẹ́ rẹ, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kọ̀.