Matthew 24:29 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Lẹsẹkẹsẹ lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, oòrùn yóo ṣókùnkùn, òṣùpá kò ní tan ìmọ́lẹ̀ rẹ̀, àwọn ìràwọ̀ yóo jábọ́ láti ọ̀run. Gbogbo àwọn agbára tí ó wà ní ọ̀run ni a óo mì jìgìjìgì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Lojukanna lẹhin ipọnju ọjọ wọnni li õrùn yio ṣõkun, oṣupá kì yio si fi imọlẹ rẹ̀ hàn, awọn irawọ yio ti oju ọrun já silẹ, agbara oju ọrun li a o si mì titi:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Lójú kan náà lẹ́yìn ìpọ́njú ọjọ́ wọ̀n-ọn-nì, “ ‘ni oòrùn yóò ṣókùnkùn, òṣùpá kì yóò sì fi ìmọ́lẹ̀ rẹ hàn; àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run yóò já sílẹ̀, agbára ojú ọ̀run ni a ó mì tìtì.’