Matthew 24:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Àmì Ọmọ-Eniyan yóo wá yọ ní ọ̀run. Gbogbo àwọn ẹ̀yà ayé yóo figbe ta, wọn yóo rí Ọmọ-Eniyan tí ó ń bọ̀ lórí ìkùukùu ní ọ̀run pẹlu agbára ògo ńlá.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li àmi Ọmọ-enia yio si fi ara hàn li ọrun; nigbana ni gbogbo ẹya aiye yio kãnu, nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà ni àmì Ọmọ-Ènìyàn yóò si fi ara hàn ní ọ̀run, nígbà náà ni gbogbo ẹ̀yà ayé yóò káàánú, wọn yóò sì rí Ọmọ-Ènìyàn tí yóò máa ti ojú ọ̀run bọ̀ ti òun ti ògo àti agbára ńlá.