Matthew 24:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Àkókò ń bọ̀ tí ẹ óo gbúròó ogun ati ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ogun. Ẹ má bẹ̀rù. Èyí níláti rí bẹ́ẹ̀, ṣugbọn kò ì tíì tó àkókò tí òpin ayé yóo dé.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin o si gburo ogun ati idagìri ogun: ẹ kiyesi i ki ẹnyin ki o máṣe jaiyà: nitori gbogbo nkan wọnyi ko le ṣe ki o ma ṣẹ, ṣugbọn opin ki iṣe isisiyi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ẹ ó máa gbọ́ ìró ogun àti ìdágìrì ogun, kí ẹ̀yin má se jáyà nítorí nǹkan wọ̀nyí kò lè ṣe kí ó ma ṣẹlẹ̀, ṣùgbọ́n òpin kì í ṣe àkókò náà.