Matthew 25:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oluwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, a óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa rẹ̀ wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ: iwọ ṣe olõtọ, ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwo bọ́ sinu ayọ̀ Oluwa rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́: ìwọ ṣe olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’