Matthew 25:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Oluwa rẹ̀ sọ fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ olóòótọ́ ẹrú, eniyan rere ni ọ́. O ti ṣe olóòótọ́ ninu nǹkan kékeré, n óo fi ọ́ ṣe alámòójútó nǹkan pupọ. Bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa rẹ̀ si wi fun u pe, O ṣeun, iwọ ọmọ-ọdọ rere ati olõtọ; iwọ ṣe olõtọ ninu ohun diẹ, emi o mu ọ ṣe olori ohun pipọ: iwọ bọ́ sinu ayọ̀ oluwa rẹ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ-ọ̀dọ̀ rere àti olóòótọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòótọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’