Matthew 25:26 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Olúwa rẹ̀ dá a lóhùn pé, ‘Ìwọ olubi ati onímẹ̀ẹ́lẹ́ ẹrú yìí. O mọ̀ pé èmi a máa kórè níbi tí n kò fúnrúgbìn sí, ati pé èmi a máa fojú wá nǹkan níbi tí n kò fi pamọ́ sí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Oluwa rẹ̀ si dahùn o wi fun u pe, Iwọ ọmọ-ọdọ buburu ati onilọra, iwọ mọ̀ pe emi nkore nibiti emi kò funrugbin si, emi si nṣà nibiti emi kò fẹ́ka si:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ṣùgbọ́n olúwa rẹ̀ dáhùn pé, ‘Ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé èmi ń kórè níbi tí èmi kò fúnrúgbìn sì, èmi sì ń kó jọ níbi tí èmi kò ó ká sí.