Matthew 25:37 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà náà ni àwọn olódodo yóo dáhùn pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a fún ọ ní oúnjẹ, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́ tí a fún ọ ní omi mu?
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana li awọn olõtọ yio da a lohun wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, ti awa fun ọ li onjẹ? tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, ti awa fun ọ li ohun mimu?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà ni àwọn olódodo yóò fèsì pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tí a sì fún ọ ní oúnjẹ? Tàbí tí òrùngbẹ ń gbẹ ọ́ tí a sì fún ọ ní ohun mímu?