Matthew 25:44 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Nígbà náà ni àwọn náà yóo bi í pé, ‘Oluwa, nígbà wo ni a rí ọ tí ebi ń pa ọ́, tabi tí òùngbẹ ń gbẹ ọ́, tabi tí o jẹ́ àlejò, tabi tí o wà ní ìhòòhò, tabi tí o ṣàìsàn, tabi tí o wà lẹ́wọ̀n, tí a kò bojútó ọ?’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni awọn pẹlu yio dahùn wipe, Oluwa, nigbawo li awa ri ti ebi npa ọ, tabi ti ongbẹ ngbẹ ọ, tabi ti iwọ jẹ alejò, tabi ti iwọ wà ni ìhoho, tabi ninu aisan, tabi ninu tubu, ti awa kò si ṣe iranṣẹ fun ọ?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nígbà náà wọn yóò dáhùn pé, ‘Olúwa, nígbà wo ni àwa rí ọ, tí ebi ń pa ọ́ tàbí tí òrùngbẹ ń gbẹ ọ́, tàbí tí o ṣàìsàn, tàbí tí o wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, tí a kò sí ràn ọ́ lọ́wọ́?’