Matthew 26:18 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó bá dáhùn pé, “Ẹ lọ sí ọ̀dọ̀ ọkunrin kan báyìí nígboro kí ẹ sọ fún un pé, ‘Olùkọ́ni ní: Àkókò mi súnmọ́ tòsí; ní ilé rẹ ni èmi ati àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi yóo ti jẹ àsè Ìrékọjá.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wipe, Ẹ wọ̀ ilu lọ si ọdọ ọkunrin kan bayi, ẹ si wi fun u pe, Olukọni wipe, Akokò mi sunmọ etile; emi o ṣe ajọ irekọja ni ile rẹ pẹlu awọn ọmọ-ẹhin mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì dáhùn pé, “Ẹ wọ ìlú lọ, ẹ̀yin yóò rí ọkùnrin kan, ẹ wí fún un pé, ‘Olùkọ́ wa wí pé: Àkókò mi ti dé. Èmi yóò sì jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi ní ilé rẹ.’ ”