Matthew 26:2 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ẹ mọ̀ pé lẹ́yìn ọjọ́ meji ni Àjọ̀dún Ìrékọjá, a óo fi Ọmọ-Eniyan lé àwọn ọ̀tá lọ́wọ́ láti kàn mọ́ agbelebu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹnyin mọ̀ pe lẹhin ọjọ meji ni ajọ irekọja, a o si fi Ọmọ-enia le ni lọwọ, lati kàn a mọ agbelebu.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Bí ẹ̀yin tí mọ̀ ní ọjọ́ méjì sí i, àjọ ìrékọjá yóò bẹ̀rẹ̀. Àti pé, a ó fi Ọmọ-Ènìyàn lé ni lọ́wọ́, a ó sì kàn mí mọ́ àgbélébùú.”