Matthew 26:31 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà náà Jesu sọ fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ óo pada lẹ́yìn mi ní alẹ́ yìí, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Ọwọ́ yóo tẹ olùṣọ́-aguntan, gbogbo agbo aguntan ni a óo fọ́nká!’
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Gbogbo nyin ni yio kọsẹ̀ lara mi li oru yi: nitoriti a ti kọwe rẹ̀ pe, Emi o kọlù oluṣọ-agutan, a o si tú agbo agutan na ká kiri.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jésù wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni yóò kọsẹ̀ lára mi ní òru òní. Nítorí a ti kọ ọ́ pé: “ ‘Èmi yóò kọlu olùsọ́ àgùntàn a ó sì tú agbo àgùntàn náà ká kiri.’