Matthew 26:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Ó tún lọ gbadura lẹẹkeji. Ó ní, “Baba mi, bí kò bá ṣeéṣe pé kí ife kíkorò yìí fò mí ru, tí ó jẹ́ ohun tí ó níláti ṣẹlẹ̀ sí mi, ìfẹ́ tìrẹ ni ṣíṣe.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si tún pada lọ li ẹrinkeji, o si ngbadura, wipe, Baba mi, bi ago yi kò ba le ré mi kọja bikoṣepe mo mu u, ifẹ tirẹ ni ki a ṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó tún fi wọ́n sílẹ̀ nígbà kejì, ó sí gbàdúrà pé, “Baba mi, bí aago yìí kò bá lè ré mi lórí kọjá àfi tí mo bá mu ún, ìfẹ́ tìrẹ ni kí a ṣe.”