Matthew 26:47 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí Jesu ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ni Judasi, ọ̀kan ninu àwọn mejila yọ, pẹlu ọ̀pọ̀ eniyan tí wọ́n mú idà ati kùmọ̀ lọ́wọ́. Wọ́n ń bọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o si ti nsọ lọwọ, wo o, Judasi, ọkan ninu awọn mejila de, ati ọ̀pọ enia pẹlu rẹ̀ ti awọn ti idà pẹlu ọgọ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn àgba awọn enia wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó ti ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, Júdásì, ọ̀kan nínú àwọn méjìlá dé pẹ̀lú ọ̀pọ̀ ènìyàn pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ lọ́wọ́ wọn, wọ́n ti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfàá àti àgbààgbà Júù wá.