Matthew 26:51 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ọ̀kan ninu àwọn tí ó wà pẹlu Jesu bá na ọwọ́, ó fa idà yọ, ó sì fi ṣá ẹrú Olórí Alufaa kan, ó gé e létí.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Si wo o, ọkan ninu awọn ti o wà pẹlu Jesu nà ọwọ́ rẹ̀, o si fà idà rẹ̀ yọ, o si ṣá ọkan ti iṣe ọmọ-ọdọ olori alufa, o si ke e li etí sọnù.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Sì wò ó, ọ̀kan nínú àwọn tí ó wà pẹ̀lú Jésù na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà yọ, ó sì ṣá ọ̀kan tí i ṣe ọmọ-ọ̀dọ̀ olórí àlùfáà, ó sì gé e ní etí sọnù.