Matthew 26:55 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Jesu bá sọ fún àwọn eniyan náà pé, “Ẹ jáde wá mú mi pẹlu idà ati kùmọ̀ bí ìgbà tí ẹ wá mú olè. Ojoojumọ ni mò ń jókòó ninu Tẹmpili láti kọ́ àwọn eniyan. Ẹ kò mú mi nígbà náà!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ni wakati na ni Jesu wi fun ijọ enia pe, Emi li ẹnyin jade tọ̀ wá bi olè, ti ẹnyin ti idà ati ọgọ lati mu? li ojojumọ li emi mba nyin joko ni tẹmpili ti emi nkọ́ nyin, ẹnyin kò si gbé ọwọ́ le mi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà náà ni Jésù wí fún ìjọ ènìyàn náà pé, “Tàbí èmi ni ẹ kà sí ọ̀daràn ti ẹ múra pẹ̀lú idà àti kùmọ̀ kí ẹ tó lé mú mi? Ẹ rántí pé mo ti wà pẹ̀lú yín, tí mo ń kọ́ yín lójoojúmọ́ nínú tẹ̀ḿpìlì, ẹ̀yin kò sì mú mi nígbà náà.