Matthew 26:69 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Peteru jókòó lóde ní àgbàlá. Ọ̀kan ninu àwọn iranṣẹbinrin wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó ní, “Ìwọ náà wà pẹlu Jesu ará Galili.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Peteru joko lode li ãfin: nigbana ni ọmọbinrin kan tọ̀ ọ wá, o wipe, Iwọ pẹlu wà pẹlu Jesu ti Galili.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Lákòókò yìí, bí Pétérù ti ń jókòó ní ọgbà ìgbẹ́jọ́, ọmọbìnrin kan sì tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Ìwọ wà pẹ̀lú Jésù ti Gálílì.”