Matthew 27:1 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, gbogbo àwọn olórí alufaa ati àwọn àgbà ìlú jọ forí-korí nípa ọ̀ràn Jesu, kí wọ́n lè pa á.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
NIGBATI o di owurọ̀, gbogbo awọn olori alufa ati awọn àgbãgba gbìmọ si Jesu lati pa a:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ní òwúrọ̀, gbogbo àwọn olórí àlùfáà àti àwọn àgbààgbà Júù tún padà láti gbìmọ bí wọn yóò ti ṣe pa Jésù.