Matthew 27:17 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí àwọn Juu pésẹ̀, Pilatu bi wọ́n pé, “Ta ni kí n dá sílẹ̀ fun yín, Jesu Baraba ni tabi Jesu tí ó ń jẹ́ Mesaya?”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina nigbati nwọn pejọ, Pilatu wi fun wọn pe, Tali ẹnyin nfẹ ki emi dá silẹ fun nyin? Barabba, tabi Jesu ti a npè ni Kristi?
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọ̀pọ̀ ènìyàn ti pé jọ ṣíwájú ilé Pílátù lówúrọ̀ ọjọ́ náà, ó béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ta ni ẹ̀yin ń fẹ́ kí n dá sílẹ̀ fún yín, Bárábbà tàbí Jésù, ẹni tí ń jẹ́ Kírísítì?”