Matthew 27:19 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí Pilatu jókòó lórí pèpéle ìdájọ́, iyawo rẹ̀ ranṣẹ sí i, ó ní, “Má ṣe lọ́wọ́ ninu ọ̀ràn ọkunrin olódodo yìí. Nítorí pé mọ́jú òní, ojú mi rí nǹkan lójú àlá nípa rẹ̀.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati o si joko lori itẹ́ idajọ, aya rẹ̀ ransẹ si i, wipe, Máṣe li ọwọ́ ninu ọ̀ran ọkunrin olododo nì: nitori ìyà ohun pipọ ni mo jẹ li oju àlá loni nitori rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí Pílátù sì ti ṣe jókòó lórí ìtẹ́ ìdájọ́ rẹ̀, ìyàwó rẹ̀ ránṣẹ́ sí i pé, “Má ṣe ní ohun kankan ṣe pẹ̀lú ọkùnrin aláìṣẹ̀ náà. Nítorí mo jìyà ohun púpọ̀ lójú àlá mi lónìí nítorí rẹ̀.”