Matthew 27:32 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nígbà tí wọn ń jáde lọ, wọ́n rí ọkunrin kan ará Kirene tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Simoni. Wọ́n bá fi ipá mú un láti ru agbelebu Jesu.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi nwọn si ti jade, nwọn ri ọkunrin kan ara Kirene, ti njẹ Simoni: on ni nwọn fi agbara mu lati rù agbelebu rẹ̀.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí wọ́n sì ti ń jáde, wọ́n rí ọkùnrin kan ará Kíréné tí à ń pè ní Símónì. Wọ́n sì mú ọkùnn náà ní túlààsì láti ru àgbélébùú Jésù.