Matthew 27:40 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
wọ́n ń sọ pé, “Ìwọ tí yóo wó Tẹmpili, tí yóo tún un kọ́ ní ọjọ́ mẹta, gba ara rẹ là. Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́, sọ̀kalẹ̀ kúrò lórí agbelebu.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Wipe, Iwọ ti o wó tẹmpili, ti o si kọ́ ọ ni ijọ mẹta, gbà ara rẹ là. Bi iwọ ba ṣe Ọmọ Ọlọrun, sọkalẹ lati ori agbelebu wá.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Ìwọ tí yóò wó tẹ́ḿpìlì, ìwọ tí yóò sì tún un mọ ní ọjọ́ kẹta. Bí ó bá jẹ́ pé Ọmọ-Ọlọ́run ni ìwọ, sọ̀ kalẹ̀ láti orí igi àgbélébùú, kí ó sì gba ara rẹ là!”