Matthew 27:42 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Àwọn ẹlòmíràn ni ó rí gbà là, kò lè gba ara rẹ̀ là. Ṣé ọba Israẹli ni! Kí ó sọ̀kalẹ̀ nisinsinyii láti orí agbelebu, a óo gbà á gbọ́.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O gbà awọn ẹlomiran là; ara rẹ̀ ni kò le gbalà. Ọba Israeli sa ni iṣe, jẹ ki o sọkalẹ lati ori agbelebu wá nisisiyi, awa o si gbà a gbọ́.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Wọ́n kẹ́gàn Rẹ̀ pé, “Ó gba àwọn ẹlòmíràn là, kò sí lè gba ara rẹ̀. Ìwọ ọba àwọn Ísírẹ̀lì? Sọ̀ kalẹ̀ láti orí àgbélébùú nísinsìn yìí, àwa yóò sì gbà ọ́ gbọ́.