Matthew 27:54 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nígbà tí ọ̀gágun ati àwọn tí ó wà pẹlu rẹ̀ tí wọn ń ṣọ́ Jesu rí ilẹ̀ tí ó mì ati gbogbo ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọ́n pupọ. Wọ́n ní, “Nítòótọ́ Ọmọ Ọlọrun ni ọkunrin yìí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nigbati balogun ọrún, ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀, ti nwọn nṣọ́ Jesu, ri isẹlẹ na, ati ohun wọnni ti ó ṣẹ̀, èru ba wọn gidigidi, nwọn wipe, Lõtọ Ọmọ Ọlọrun li eyi iṣe.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nígbà tí balógun ọ̀run àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ tí wọ́n ń ṣọ Jésù rí bí ilẹ̀ ṣe mì tìtì àti ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ẹ̀rù bà wọn gidigidi, wọ́n wí pé, “Lóòótọ́ ọmọ Ọlọ́run ní í sẹ!”