Matthew 27:64 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Nítorí náà, pàṣẹ kí wọ́n ṣọ́ ibojì náà títí di ọjọ́ kẹta. Bí a kò bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ lè wá jí òkú rẹ̀ lọ, wọn yóo wá wí fún àwọn eniyan pé, ‘Ó ti jinde kúrò ninu òkú.’ Ìtànjẹ ẹẹkeji yóo wá burú ju ti àkọ́kọ́ lọ.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina paṣẹ ki a kiyesi ibojì na daju titi yio fi di ijọ kẹta, ki awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ máṣe wá li oru, nwọn a si ji i gbé lọ, nwọn a si wi fun awọn enia pe, O jinde kuro ninu okú: bẹ̃ni ìṣina ìkẹhìn yio si buru jù ti iṣaju.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nítorí náà, pàṣẹ kí a ti ibojì rẹ̀ gbọn-ingbọn-in títí ọjọ́ kẹta, kí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ má ṣe wá jí i gbé lọ, wọn a sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ fún gbogbo ènìyàn pé, ‘Òun ti jíǹde,’ Bí èyí bá ní láti ṣẹlẹ̀, yóò burú fún wa púpọ̀ ju ti àkọ́kọ́ lọ.”