Matthew 28:7 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ẹ lọ sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ wéré, pé ó ti jí dìde kúrò ninu òkú. Ó ti ṣáájú yín lọ sí Galili; níbẹ̀ ni ẹ óo ti rí i. Ohun tí mo ní sọ fun yín nìyí.”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ẹ si yara lọ isọ fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, o ti jinde kuro ninu okú; wo o, ó ṣãju nyin lọ si Galili; nibẹ̀ li ẹnyin o gbé ri i: wo o, mo ti sọ fun nyin.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Nísinsìn yìí, Ẹ lọ kíákíá láti sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Rẹ̀ pé, ‘Ó ti jíǹde kúrò nínú òkú. Àti pé òun ń lọ sí Gálílì síwájú yín, níbẹ̀ ni ẹ̀yin yóògbé rí i, wò ó, o ti sọ fún yin”.