Matthew 4:21 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Bí ó ti kúrò níbẹ̀ tí ó lọ siwaju díẹ̀ sí i, ó rí àwọn arakunrin meji mìíràn, Jakọbu ọmọ Sebede ati Johanu arakunrin rẹ̀. Wọ́n wà ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó bá pè wọ́n.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi o si ti ti ibẹ lọ siwaju, o ri awọn arakunrin meji, Jakọbu ọmọ Sebede, ati Johanu arakunrin rẹ̀, ninu ọkọ̀ pẹlu Sebede baba wọn, nwọn ndí àwọn wọn; o si pè wọn.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ó sì ti kúrò ní ibẹ̀, ò rí àwọn arákùnrin méjì mìíràn, Jákọ́bù ọmọ Sébédè àti Jòhánù, arákùnrin rẹ̀. Wọ́n wà nínú ọkọ̀ ojú-omi pẹ̀lú Sébédè baba wọn, wọ́n ń dẹ àwọ̀n wọn, Jésù sì pè wọn náà pẹ̀lú.