Matthew 4:23 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Jesu wá ń kiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ àwọn eniyan ninu ilé ìpàdé wọn, ó ń waasu ìyìn rere ìjọba Ọlọrun, ó tún ń wo oríṣìíríṣìí àrùn sàn lára àwọn eniyan.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Jesu si rìn ni gbogbo ẹkùn Galili, o nkọni ni sinagogu wọn, o si nwasu ihinrere ijọba, o si nṣe iwosàn gbogbo àrun ati gbogbo àisan li ara awọn enia.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Jésù sì rin káàkiri gbogbo Gálílì, ó ń kọ́ni ní sínágọ́gù, ó ń wàásù ìyìn rere ti ìjọba ọ̀run. ó sì ń ṣe ìwòsàn àrùn gbogbo àti àìsàn láàrin gbogbo ènìyàn.