Matthew 4:6 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ó sọ fún un pé, “Bí Ọmọ Ọlọrun bá ni ọ́ nítòótọ́, bẹ́ sílẹ̀. Nítorí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé, ‘Yóo pàṣẹ fún àwọn angẹli rẹ̀ nítorí rẹ, kí wọ́n tẹ́wọ́ gbà ọ́, kí o má baà fi ẹsẹ̀ gbún òkúta.’ ”
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
O si wi fun u pe, Bi iwọ ba iṣe Ọmọ Ọlọrun, bẹ́ silẹ fun ara rẹ: A sá ti kọwe rẹ̀ pe, Yio paṣẹ fun awọn angẹli rẹ̀ nitori rẹ, li ọwọ́ wọn ni nwọn o si gbé ọ soke, ki iwọ ki o má ba fi ẹsẹ rẹ gbún okuta.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ó wí pé, “Bí ìwọ̀ bá jẹ́ ọmọ Ọlọ́run, Bẹ́ sílẹ̀ fún ara rẹ. A sa ti kọ̀wé rẹ̀ pé: “ ‘Yóò pàṣẹ fún àwọn ańgẹ́lì rẹ̀ nítorí tìrẹ wọn yóò sì gbé ọ sókè ni ọwọ́ wọn kí ìwọ kí ó má baà fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta.’ ”