Matthew 5:11 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Ayọ̀ ń bẹ fun yín, tí wọ́n bá kẹ́gàn yín, tí wọ́n ṣe inúnibíni si yín, tí wọ́n bá ń fi èké sọ ọ̀rọ̀ burúkú lóríṣìíríṣìí si yín nítorí mi.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Alabukún-fun li ẹnyin, nigbati nwọn ba nkẹgan nyin, ti nwọn ba nṣe inunibini si nyin, ti nwọn ba nfi eke sọ̀rọ buburu gbogbo si nyin nitori emi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Alábùkún-fún ni ẹ̀yin nígbà tí àwọn ènìyàn bá fi àbùkù kàn yín tí wọn bá ṣe inúnibíni sí yín, ti wọn fi ètè èké sọ̀rọ̀ búburú gbogbo sí yín nítorí mi.