Matthew 5:22 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn èmi wá ń sọ fún yín pé, ẹni tí ó bá bínú sí arakunrin rẹ̀ yóo bọ́ sinu ẹjọ́. Ẹni tí ó bá bú arakunrin rẹ̀, yóo jẹ́jọ́ níwájú àwọn ìgbìmọ̀ ìlú. Ẹni tí ó bá sọ fún arakunrin rẹ̀ pé, ‘Ìwọ òmùgọ̀ yìí’ yóo wà ninu ewu iná ọ̀run àpáàdì.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn emi wi fun nyin, ẹnikẹni ti o binu si arakunrin rẹ̀ lasan, yio wà li ewu idajọ; ati ẹnikẹni ti o ba wi fun arakunrin rẹ̀ pe, Alainilari, yio wà li ewu ajọ awọn igbimọ; ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba wipe, Iwọ aṣiwere, yio wà li ewu iná ọrun apadi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n èmi wí fún un yín pé, ẹnikẹ́ni tí ó bínú sí arákùnrin rẹ̀ yóò wà nínú ewu ìdájọ́. Ẹnikẹ́ni ti ó ba wí fun arakùnrin rẹ̀ pé, ‘Ráákà’ yóò fara hàn níwájú Sahẹ́ńdìrì; ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá wí pé ‘Ìwọ wèrè!’ yóò wà nínú ewu iná ọ̀run àpáàdì.