Matthew 5:30 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
Bí ọwọ́ ọ̀tún rẹ bá mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù. Ó sàn fún ọ kí ọ̀kan ninu àwọn ẹ̀yà ara rẹ ó ṣègbé jù kí gbogbo ara rẹ lọ sí ọ̀run àpáàdì lọ.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Bi ọwọ́ ọtún rẹ ba mu ọ kọsẹ̀, ke e kuro, ki o si sọ ọ nù; o sá li ère fun ọ, ki ẹ̀ya ara rẹ kan ki o ṣegbé, jù ki a gbe gbogbo ara rẹ jù si iná ọrun apadi.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Bí ọwọ́ rẹ ọ̀tún bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀ gé e kúrò, kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó sàn kí ẹ̀ya ara rẹ kan ṣègbé ju kí gbogbo ara rẹ lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì.