Matthew 5:45 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ti di ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run. Nítorí a máa mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn eniyan burúkú ati àwọn eniyan rere; a sì máa rọ òjò sórí àwọn olódodo ati sórí àwọn alaiṣododo.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ki ẹnyin ki o le mã jẹ ọmọ Baba nyin ti mbẹ li ọrun: nitoriti o nmu õrùn rẹ̀ ràn sara enia buburu ati sara enia rere, o si nrọ̀jo fun awọn olõtọ ati fun awọn alaiṣõtọ.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Kí ẹ̀yin lè jẹ́ ọmọ Baba yín bi ń bẹ ní ọ̀run. Ó mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sára ènìyàn búburú àti ènìyàn rere, ó rọ̀jò fún àwọn olódodo àti fún àwọn aláìṣòdodo.