Matthew 6:23 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
Ṣugbọn bí ojú rẹ kò bá ríran tààrà, gbogbo ara rẹ ni yóo ṣókùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ tí ó wà ninu rẹ bá wá di òkùnkùn, báwo ni òkùnkùn náà yóo ti pọ̀ tó!
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ṣugbọn bi oju rẹ ba ṣõkùn, gbogbo ara rẹ ni yio kun fun òkunkun. Njẹ bi imọlẹ ti mbẹ ninu rẹ ba jẹ́ òkunkun, òkunkun na yio ti pọ̀ to!
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
Ṣùgbọ́n bí ojú rẹ kò bá dára, gbogbo ara rẹ ni yóò kún fún òkùnkùn. Bí ìmọ́lẹ̀ ti ó wà nínú rẹ bá wáá jẹ́ òkùnkùn, òkùnkùn náà yóò ti pọ̀ tó!