Matthew 6:24 — Compare Translations
3 translations compared side by side
Yoruba 2010
“Kò sí ẹni tí ó lè sin oluwa meji. Nítorí ọ̀kan ni yóo ṣe: ninu kí ó kórìíra ọ̀kan, kí ó fẹ́ràn ekeji, tabi kí ó fara mọ́ ọ̀kan, kí ó má ka ekeji sí. Ẹ kò lè sin Ọlọrun, kí ẹ tún máa bọ owó.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Ko si ẹniti o le sìn oluwa meji: nitori yala yio korira ọkan, yio si fẹ ekeji; tabi yio faramọ ọkan, yio si yàn ekeji ni ipọsi. Ẹnyin ko le sìn Oluwa pẹlu mammoni.
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Kò sìí ẹnìkan tí ó lè sin ọ̀ga méjì. Òun yóò yà kórìíra ọ̀kan tí yóò fẹ́ràn èkejì, tàbí kí ó fara mọ́ ọ̀kan kí ó sì yan èkejì ní ìpọ̀sì. Ẹ̀yin kò lè sin Ọlọ́run àti owó papọ̀.