Matthew 7:24 — Compare Translations

3 translations compared side by side

Yoruba 2010
“Nítorí náà, gbogbo ẹni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ mi yìí, tí ó bá fi ṣe ìwà hù dàbí ọlọ́gbọ́n eniyan kan, tí ó kọ́ ilé rẹ̀ sórí àpáta.
Yoruba YBCV (Bibeli Mimọ)
Nitorina ẹnikẹni ti o ba gbọ́ ọ̀rọ temi wọnyi, ti o ba si ṣe wọn, emi o fi wé ọlọ́gbọn enia kan, ti o kọ́ ile rẹ̀ si ori àpata:
Yoruba YCB (Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní)
“Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá gbọ́ ọ̀rọ̀ tèmi wọ̀nyí, tí ó bá sì ṣe wọn, èmi ó fi wé ọlọ́gbọ́n ènìyàn kan, ti ó kọ́ ilé rẹ̀ sí orí àpáta.